Saturday, December 5, 2020
Home Iroyin Ilé Aṣòfin Èkó yóò ṣàtúnṣe sòfin tó lòdì sí ìlòkùlo oògùn, rọ...

Ilé Aṣòfin Èkó yóò ṣàtúnṣe sòfin tó lòdì sí ìlòkùlo oògùn, rọ ìjọba àti òbí láti ṣohun tó tọ́


Ilé Aṣòfin Èkó yóò ṣàtúnṣe sòfin tó lòdì sí ìlòkùlo oògùn, rọ ìjọba àti òbí láti ṣohun tó tọ

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ti pe Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ti Ìpínlẹ̀ Èkó lati b́a àwọn Alákóso-àgbà fún Ètò Ẹ̀kọ́, fún Ètò Ìròyìn àti Ọgbọ́n ìṣèlú àti fún tọrọ Ọ̀dọ́ àti Ìdàgbàsókè Awùjọ pẹ̀lú àwọn mìíràn tó yẹ láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìlánilọ́yẹ lóríṣííríṣi tako ìwà ìlòkúlò oògùn ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ilé-ẹ̀kọ́ girama, ilé-ẹ̀kọ́gíga àti àwọn akẹkọọ miiran ni Ìpínlẹ̀ Èkó.

Ẹni to da aba naa, ti wọn pe akori rẹ ni “Ipe si Ijọba Ipinlẹ Eko lati bẹrẹ eto Ilanilọyẹ tako ilokulo oogun ni awọn ile-ẹkọ girama ni ipinlẹ yii”, Aṣofin Desmond Elliot rọ Ile Igbimọ Aṣofin yii lati pe Alaga Ikọ ẹṣọ Pataki fun awọn iwa to tako ayika ati ẹsun pataki miiran lati gbe igbesẹ to nipọn lori bi awọn kan ṣe n ta awọn oogun oloro ni ayika awọn ile-iwe, ki wọn si ri i daju pe gbogbo ẹka ile-iṣẹ ijọba to yẹ ni wọn tẹle ipinnu Ile naa. O ni:

“Ki Alakoso-agba fun awọn ọlọpaa ni Ipinlẹ yii maa ṣọ awọn ayika awọn ile-ẹkọ gbogbo, nipa pipaṣẹ fun awọn ọlọpaa abẹ rẹ lati ri i daju pe wọn ko ta iru awọn oogun oloro bayii ni ayika ile-iwe. A tun rọ awọn obi lati maa ṣọ awọn ọmọ lọwọ lẹsẹ lati le ṣadinku bi wọn ṣe n lo oogun oloro bayii lawujọ”

“O ti farahan pe atunbọtan awọn oogun lile ti awọn akẹkọọ n lo n ṣe ipalara fun ẹkọ wọn ni ile-iwe, to si n jẹ ki iwa ipa peleke sii lawujọ, bii ẹgbẹ okunkun, fifipa-ba-ni-lopọ ati ẹgbẹ buruku. Iru ilanilọyẹ bayii yoo ṣe pataki, paapaa ni asiko yii ti awọn akẹkọọ yii n pada wọle lẹyin ti wọn ti ti awọn ile-iwe pa fun ọjọ pipẹ latari arun COVID-19.”

Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ aṣofin yii to wa nijokoo ni wọn gba aba naa wọle gẹgẹ bi ipinnu ti Ile Igbimọ Aṣofin naa fọwọ si.

Agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa fi mulẹ pe ọwọ ti awọn ọdọ ode iwoyi fi n lo oogun oloro buru jai. O ni:

“Ki awọn alaṣẹ ile-iwe maa fimu finlẹ lati ṣọ awọn akẹkọọ yii, tori a o le ni ki awọn to n taja ni awọn agbegbe yii ma ṣowo wọn. Sibẹ aba yii dara lati fi ṣatunṣe si iwa awọn ọmọde yii ni gbagede ile-iwe ati nita rẹ”

“Ki awọn obi funra wọn maa fimu finlẹ lati tete fura bi awọn ọmọ wọn ba fẹ maa lo awọn oogun oloro yii. Bakan naa ni wọn yoo fọwọ ofin mu obi ti ọwọ ba ọmọ rẹ pe o lọwọ ninu iwa lilo oogun oloro. Awọn ẹṣọ oju ọna naa maa n mọ siru iwa bayii, paapaa ti wọn maa n gba awọn eniyan kan laaye lati lo gbagede ile-iwe lalaalẹ. Ki ijọba maa mojuto bi wọn yoo ṣe maa gba awọn ẹsọ si awọn ile-iwe.”

Igbakeji agbẹnusọ Ile Igbimọ Aṣofin yii, Aṣofin Eshinlokun-Sanni fi kun un pe bi wọn ṣe n lo oogun oloro ni ipinlẹ yii pọ ju tawọn ibomiran ni orilẹ-ede Naijiria lọ. O fi mulẹ pe bii iko mọkandinlaadọta ninu ida ọgọrun-un (69%) ni awọn ọdọ to n lọwọ ninu ilokulo oogun ni ipinlẹ yii. O ni:

“A gbọ pe awọn oogun lile ti a mọ si ‘tramadol, codeine ni awọn ọdọ n lo nilokulo bayii. Oṣere ọmọ orilẹ-ede naijiria kan sọ pe ọrọ ilokulo oogun dabii epe, o yẹ ki a le tete re epe naa. Fun idi eyi, mo fara mọ aba yii, ṣugbọn a le kan si igbimọ awọn olutọju alaisan naa, ki wọn le ri sọrọ awọn ayederu oṣiṣẹ to wa laarin wọn ti wọn n ṣatilẹyin fun lilo iru awon oogun bayii.”

Aṣofin Abiọdun Tọbun sọ pe iru iwa bayii bẹrẹ lati ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ, wọn si ni lati tete pana rẹ nibẹ. O ni:

“Ọpọ awọn ọdọ lo ro pe iru awọn oogun yii maa n fun wọn lagbara lati le ni igboya ati ọkan lile. Fun idi eyi wọn ni lati la wọn lọyẹ. Awọn ikọ ẹsọ gbọdọ ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lori awọn to n ta iru awọn oogun bayii, ki wọn si ṣawari awọn kọrọ ti wọn ti n lo awọn oogun yii laarin adugbo. A gbọdọ tete fopin si iwa yii, nitori awọn ọdọ yii ni yoo gba ipo asiwaju lọwọ wa lọla.”

Aṣiwaju ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju ninu Ile, Aṣofin Sanai Agunbiade sọ pe ohun ti o tun n fa iwa ilokulo oogun yii ni awọn ohun ti awọn ọmọ n ri lori awọn ẹrọ ayelujara. Ki awọn eniyan maa wọ awọn orin ati nnkan ti awọn ọmọ n gbọ tabi wo.

Awọn aṣofin miiran ti wọn tun ṣatilẹyin fun aba yii ni Aṣofin Moshood Oshun, Aṣofin Gbolahan Yishawu, Aṣofin Bisi Yusuff, Aṣofin David Setonji, Aṣofin Temitọpẹ Adewale, Aṣofin Ganiyu Ọkanlawọn, Aṣofin Adedamọla Richard.      

Lanre Lagada-Abayọmi

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.

Most Popular

Recent Comments

%d bloggers like this: