Saturday, November 28, 2020
Home Iroyin Ẹ jẹ kí àtúnṣe bá ètò ààbò ní apá ìwọ oòrùn

Ẹ jẹ kí àtúnṣe bá ètò ààbò ní apá ìwọ oòrùn


Ẹ jẹ kí àtúnṣe bá ètò ààbò ní apá ìwọ oòrùn

Àwọn gómìnà, mínísítà àti àwọn ìgbìmọ lọbalọba ní  apá ìwọ oòrùn orílẹ èdè Nàíjíríà , ti rọ ìjọba àpapọ láti ṣe àtúnse tó mọnyán lórí sí ètò ààbò tó n fòníkú-fọla jìde ní apá ìwọ oòrùn orílẹ ède yìí kí ó leè gbógun ti ìwà ìdúnkoòkò mọni  àti  awọn iwa ọdaran mííràn ní apá iwọ oòrùn Nàíjíríà .

Eleyii wa lara awọn ohun ti wọn fẹnuko le lori nibi ipade ti awọn gomina,igbimọ lọba-lọba, igbimọ ijọba apapọ ati awọn minisita ṣe niluu Eko  ni apa iwọ oorun orilẹ ede Naijiria,lọjọ Aiku.

Lara awọn ti wọn bọwọlu iwe  abajade ọhun ni alaga awọn gomina ni apa iwọ oorun orilẹ ede Naijiria, ti o tun jẹ gomina ipinlẹ Ondo , Rotimi Akeredolu .

 Oba Adeyeye Ogunwusi ,Ooni ile –ifẹ to jẹ asoju fun igbimọ lọba-lọba wa dupẹ  pupọ lọwọ aarẹ  Muhammadu Buhari  fun gibesẹ to gbe lati yanju  awọn ti wọn n fẹhunu han nipa fifopin si ikọ ọlọpaa ti a mọ  si.

Lara ohun ti igbimọ ọhun fẹnuko le lori ni  pe ki awọn olọpaa tubọ wa ni awọn gbogbo igberiko to wa lorilẹ ede Najiria paapaa julọ ni awọn ẹkun orilẹ ede yii.

Igbimọ tun fẹnuko pe ki ajọse to mọnyan lori tubọ maa wa laarin awọn ọba ,ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ lori ọna lati yanju awọn ipenija to ba n dojukọ ipinlẹ onikaluku gẹgẹ bi ofin se laa silẹ nipa ojuse awọn ọba. 

Igbimọ naa tun fẹnuko pe ki ijọba apapọ bowọlu abajade ipade igbimọ asoju orilẹ ede ti wọn ṣe ni odun 2014 , ki wọn si samulo awọn ohun ti wọn fẹnuko le lori nipa eto ọrọ aje,eto aabo,iwa aparo kan ko ga ju ọkna lọ lorilẹ ede yii.

EndSARS:  

Ipade igbimọ ọhun tun bẹnu atẹ lu  bi ifẹhonuhan  wọrọwọ ti awọn ọdọ orilẹ ede lati fopi si ikọ  EndSARS sugbọn ti awọn janduku ja gba ti wọn si loo lati ba awọn ohun alumọọni , eto ọrọ aje  ati eto alaafia to n jọba ni  ni apa iwọ oorun jẹ.

 “Igbesẹ  gbọdọ wa lati dena iru isẹlẹ to waye lasiko ifẹhonuhan lati fopin ṣi ikọ ENDSARS  lorilẹ ede yii.  

A tun wa rọ gbogbo ile-isẹ ọlọpaa lati maa tete da awọn eniyan lohun lasiko ti wọn ba nilo iranwọ wọn nipa di daabo bo ẹmi ati dukia awọn eniyan.

Ààlà Títìpa

Bi wọn se ti aala orilẹ ede yii pa fun ọjọ pipẹ tun sakoba fun  eto ọrọ aje orilẹ ede yii,ni eyi ti o jẹ ki owo ori ọja tun gbẹnu soke, nitori naa igbimọ tun rọ ijọba apapọ lati tun sagbeyẹwo igbesẹ naa.

Igbimọ naa tun rọ ijọba apapọ  lati  ran awọn ijọba ipinlẹ lọwọ nipa pipese eto isẹ ati ironilagbara fun awọn ọdọ .

 “ki ijọba apapọ tun ri i pe wọn lo awọn irinsẹ eto ẹrọ igbalode fun eto aabo bi i awọnt Facebook, Twitter, Instagram abbl, lati lee maa gbogun ti awọn iroyin ẹlẹjẹ ati iroyin ti o lee fa ogun lorilẹ ede yii.”

Lasiko ti Minisita fun iroyin ati asa lorilẹ ede Naijiria,Lai Muhammed n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyi ipade  , o ni ipade ti awọn se pẹlu awọn  gomina  ati awọn adari oselu ni ẹkun iwọ oorun ni lati jọ finukonu , ki wọn si tun lo asiko naa lati ba ipinlẹ Eko  kẹdun lori ikọlu to waye latari ifẹhonuhan lori ikọ EndSARS .

Asoju osisẹ fun aarẹ  Muhammadu Buhari , ọjọgbọn Ibrahim Gambari lo soju aarẹ , pẹlu awọn igbimọ ijọba apapọ  lati ẹkun naa ati adari ile-isẹ ọlọpaa lorilẹ ede Naijiria, Muhammed Adamu,  ni wọn jọ wa nibi ipade naa to waye ni  gbọngan ile itura Banquet to wa ni , Alausa.

Akeredolu to jẹ gomina ipinlẹ Ondo ati alaga awọn gomina fun ẹkun iwọ oorun  ni ipade naa ni  se lati pese eto alaafia ni ẹkun ọhun ati lati wa ojutuu ṣi ohun to mu ki awọn ọdọ orilẹ ede ṣe fi ara wọn silẹ fun awọn ọbayejẹ orilẹ ede yii.

O ni :  loju wa bayii ni ifẹhonuhan to bẹrẹ ni wọrọwọ se di  wahala , ti wọn si bẹrẹ ṣi n ba gbogbo nnkan eto ọrọ aje jẹ.isẹlẹ yii jẹ ka mọ pe a gbọdọ wa nnkan ṣe ni kiakia lọna ti eto alaafia yoo se jọba ni ẹkun iwọ oorun Gusu orilẹ ede Naijiria.

Ọjọgbọn Gambari ti o gbẹnu aarẹ Buhari sọrọ pe ohun to fa wahala ati iwa jangudu nlatari ifẹhonuhan lati fopin si ikọ EndSARS ni nipa bi awọn oloselu ti se kọ awọn ọdọ silẹ nipa eto isejọba, o ni eto isejọba gbọdọ kuro nibi fifi ẹnu kọle fun awọn ọdọ , a gbọdọ lee ro awọn ọdọ lagbara ki a ṣi pese isẹ lọpọ janturu fun wọn. O ni aarẹ ti seleri lati satunse si gbogbo nnkan ti awọn ọdọ n beere fun.

Gomina ipinlẹ Eko , Babajide Sanwo-Olu ni ipade naa waye lasiko ti ẹkun iwọ oorun Gusu sẹsẹ bọ lọwọ ijamba to waye ni ẹkun naa.

Ademọla Adepọju

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.

Most Popular

Recent Comments

%d bloggers like this: