Friday, December 4, 2020
Home Iroyin Ààrẹ Buhari búra fún àwọn àkọ̀wé àgbà méjìlá

Ààrẹ Buhari búra fún àwọn àkọ̀wé àgbà méjìlá


Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Muhammadu Buhari ti búra fún  àwọn akọ̀wé àgbà  méjìlá fún àwọn ilé –isẹ́ àti àjọ tó wà lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà .

Aarẹ Buhari se ibura yii, ki o to bẹrẹ ipade igbimọ ijoba apapọ , ni eyi ti igbakeji aarẹ orilẹ ede Naijiria, ọjọgbọn, Yemi Osinbajo na wa nibẹ pẹlu.

losu kẹfa ni oludari awọn osisẹ ijọba apapọ lorilẹ ede Naijirias, ọmọwe Folasade Yemi-Esan kede orukọ awọn akọwe agba wọnyi ninu atẹjade kan lori ẹrọ ayelujara.

Tawọn akọwe agba tuntun ati ipinlẹ ti wọn ti wa niwọnyi: Belgore Shuaib Mohammad, Kwara; Akinlade Oluwatoyin, Kogi; Ekpa Anthonia Akpabio, Cross River; Alkali Bashir Nura, Kano; Ardo Babayo Kumo, Gombe ati Anyanwutaku lfeoma, Anambra.

awọn miran niwọnyi : Udoh Moniloja Omokunmi, Oyo; Hussaini Babangida, Jigawa; Mohammed Aliyu Ganda, Sokoto; Mahmuda Mamman, Yobe; Meribole Emmanuel Chukwuemeka, Abia ati Tarfa Yerima Peter Adamawa.

Aarẹ tun bura fun kọmisana ti yoo maa dari ile-isẹ to gba awọn osisẹ ijọba apapọ sísẹ́, Idahagbon Henry .

lara awọn minisita to wa nibi ipade igbimọ ọhun ni Minisita fun Niger Delta, Godswill Akpabio, adari eto idajọ ati minisita fun eto idajọ lorilẹ ede Naijiria, Abubakar Malami;minisita fun eto iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed; minisita fun eto inawo , isuna ati eto ilana, iyaafin Zainab Ahmed, minisita fun ilu Federal Capital Territory (FCT), Mohammed Bello, ati minisita fun eto omi , Sulieman Adamu.

lara awọn ti o tun wa nibi ipade ọhun tun ni akọwe agba fun ijọba apapọ ọgbẹni Boss Mustapha; adari osisẹ ijọba apapọ, ọjọgbọn Ibrahim Gambari; ati oluranlọwọ aarẹ nipa eto aabo ajagun fẹyinti Babagana Monguno.

Amọsa adari awọn osisẹ ijọba apapọ iyaafin , Yemi-Esan ati awọn minisita yooku darapọmọ ipade lori ẹrọ ayelujara.

Ademọla Adepọju

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.

Most Popular

Recent Comments

%d bloggers like this: